BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Wo ohun márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ofin tuntun tó rọ̀ mọ́ nọ́ńbà BVN tí Banki àpapọ̀ gbé jáde
Awọn ofin naa ti wọn ni yoo gbera sọ lọjọ akọkọ ninu oṣu Karun-un ọdun 2026, wa fun iforukọsilẹ BVN ati ki ohun gbogbo le ri bo ṣe yẹ ninu akanti rẹ.
Tọkọtaya gbajúmọ̀ òṣèré, Lateef Adedimeji àti aya rẹ̀, Adebimpe bí ìbẹta
Baba ibẹta, Lateef Adedimeji lo fi ikede naa sori ayelujara ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ ni owurọ oni, ọjọ kini osu karun ọdun 2026.
Wo bí ìfìyàjẹni àwọn ọlọ́pàá lásìkò ìwọ́de òṣìṣẹ́ ṣe bí àyájọ́ ọjọ́ òṣìṣẹ́ àti ìdí tí wọn ṣe yan ọjọ́ àkọ́kọ́ oṣù Karùn-ún
Bí òní ṣe jẹ́ ọjọ́ Kíní oṣù Karùn-ún, tíí ṣe àyàjọ́ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní àgbáyé, BBC News Yorùbá kọ ìtàn bí àyájọ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ìdí tó ṣe ń wáyé lónìí.
Kókó ọ̀rọ̀ tí Akeem, ọkọ Sisi Alagbo sọ rèé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí ẹnu ayé kun òun àti aya rẹ̀
Loju opo Facebook rẹ ni Akeem ti n bẹbẹ l'Ọjọbọ, nibẹ lo ti tọrọ aforiji lọwọ gbogbo eeyan fun fidio ibi to ti n ba Sisi Alagbo ati obinrin miran ni ajọṣepọ, to gbode kan lọjọ Aje ọsẹ yii.
Àbọ̀ ìwádìí EFCC rèé lórí Pasitọ Jerry Eze tó ní òjò Dọ́là àti Pọ́ùn ń rọ̀ sínú àkáǹtì rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà
Olukoyede sọ pe awọn pasitọ atawọn imaamu kan ni Naijiria wa lahamọ lọwọlọwọ, kootu si ti da awọn kan lẹjọ paapaa fun ajẹbanu ati jibiti lilu.
Fídíò, "Igede Ekiti ni ilé Osun, omi rẹ̀ sàn dé Osogbo ni, ohun tó mú u yíra padà kò di odò ńlá rèé", Duration 3,19
Igede Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ni odo Osun ti ṣan lọ si ilu Osogbo eyi lo si mu BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu naa lati tọpinpin rẹ.
Ọkùnrin kan hú òkú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ báńkì bíi ẹ̀rí pé ó ti kú, òun sí ló tọ́ sí láti gba owó rẹ̀
Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Munda di ẹni ti wọn n sọrọ rẹ nigba ti fidio kan to ṣafihan bo ṣe n gbe Egungun oku ẹgbọn rẹ lọ sile ifowopamọ naa gba ori ayelujara.
Bíjọba Tinubu kò ṣe rẹ́yìn ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ tó ń pa Krísítẹ́ní, a ti gé ìrànwọ́ wa sí Naijiria dé ìdajì - Amẹ́ríkà
Ofin tuntun yii lo ke si ijọba Amẹrika lati gbẹsẹle idaji owo iranwọ to yẹ ko fi ranṣẹ si ijọba Naijiria.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ dá David Mark padà bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú ADC
Tẹ o ba gbagbe, o ti ṣe diẹ ti rogbodiyan lori ta ni yoo ṣaaju awọn ẹgbẹ yii ti n waye, ti ile ẹjọ si ti sun idajọ siwaju fun awọn asiko kan.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,55
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Aráàlú dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá n'Ibadan bí ọlọ́kadà kan ṣe kú lójú pópó lásìkò táwọn ọlọ́pàá dá a dúró
Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn ọlọpaa meji kan n yẹ awọn eeyan wo nibẹ, eyii ti ofin ko gba wọn laaye lati ṣe lagbegbe ọhun.
Owó epo tó lọ sókè lọ́jà àgbáyé ṣàkóbá fún owó lítà epo ní Nàíjíríà, bí Trump ṣe ń tẹ̀síwájú láti dí epo Iran mọ́lé
Epo rọbi Brent crude wọ $119 agba kan ni irọlẹ ọjọru, eyi to jẹ alekun ida meje ni ọjọ kan ṣoṣo lati ibẹre oṣu yii.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ìdí mẹ́rin rèé táwọn ibùdó ìfọporọ̀bì Naijiria kò fi lè ṣiṣẹ́ láéláé - Obasanjo ṣàlàyé
Oloye Olusegun Obasanjo loun sọrọ yii latari nnkan ti ileeṣẹ epo rọbi Shell sọ foun lasiko toun jẹ Ààrẹ orilẹede Naijiria.
Ọ̀nà wo ni iléeṣẹ́ ológun gbà pa àgùnbánirọ̀ kan ní Abuja, tí ẹbí rẹ̀ fi fọnmú?
Awọn aworan ati fidio ti wọn fi han BBC ṣafihan bi gbogbo inu yara naa ṣe daru, ti oju ọta ibọn si wa lara ogiri ati ilẹkun inu yara naa.
"Bí ọ̀wọ́ngógó epo bàálù ṣe gbòde, àti lọ sí Hajj lọ́dún yìí di ọwọ́ Ọlọ́run àti ìjọba"
Alhaja Kaola ti wọn n pe ni Ummu-li-Muminat sọ pe awọn olujọsin ti ijọba ba ṣeranwọ owo fun nikan ni owo ti wọn ti san tẹlẹ le gbe lọ si Mecca bayii.
Wo àwọn owó àjẹmọ́nú òṣìṣẹ́ tí ìjọba àpapọ̀ ṣàfikún rẹ̀ àti ìdí tí NLC ṣe yínmú lórí àfikún náà
Ẹka to n ri si owo tawọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria n gba lo fi ikede yii lede ninu atẹjade wọn, ẹgbẹ osisẹ si fesi lori rẹ.
Kí ló fa ogun 'Wẹtiẹ' tíjọba ológun ṣe bi ìjọba alágbádá àkọ́kọ́ wó, èyí tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ àti ẹ̀kọ́ tó yẹ káwọn olóṣèlú àsìkò yìí kọ́?
BBC News Yoruba ṣe àkojọpọ itan to rọ mọ laasigbo Wẹtiẹ, idaluru to mu ọpọ ẹmi lọ nilẹ Yoruba, to si mu kawọn ologun gba ijọba, lati mu kawọn ọmọ Naijiria kẹkọọ, paapaa awọn eeyan ti ọrọ oselu gbe ru.
Àwọn ọmogun ọlọ̀tẹ̀ pa mínísítà ètò ààbò ní Mali àti ẹbí rẹ̀ mẹ́ta
Ẹbi minisita eto aabo ati ileeṣẹ iroyin France sọ pe awọn janduku agbẹbọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu al-Quaeda tun ṣekupa awọn mọlẹbi Camara mẹta ninu ikọlu ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja ni Kita.
Ọwọ́ tẹ afurasí tó yìnbọn níbi àpèjẹ akọ̀ròyìn tí Trump wá nílùú Washington
Ọpọ awọn akọroyin BBC to wa nibẹ, royin pe akọlukọgba bẹrẹ si i waye bi iro ibọn ṣe n dun ni.
Èèyàn 300 ṣe ìgbéyàwó ní Gaza láàárín ogun tó ń wáyé níbẹ̀
Ayẹyẹ ọhun to waye ni Deir al-Balah ni iroyin sọ pe wọn ti mu awọn tọkọtaya ọhun laarin eeyan ti iye wọn to ẹgbẹrun meji.
Amẹ́ríkà wọ́gilé ìjíròrò pẹ̀lú Iran, bí Iran ṣe ní àbẹ̀wò sí Pakistan kìí ṣe nítorí ogun
Trump sọ loju opo naa pe oun wọgile irinajo awọn to fẹ lọ ṣoju Amẹrika nibi ijiroro pẹlu Iran ni Pakistan nitori o jẹ fifi ọpọlọpọ akoko ṣofo ni.
Aiyedatiwa jẹ wá lówó oṣù mẹ́fa, ó tún fẹ́ lé wa níbi tí ìrandíran wa ń gbé láti 1943 - Àwọn àkàndá ẹ̀dá Ago Ireti figbeta l'Ondo
Yatọ si awon to ni arun ẹ̀tẹ̀ to n gbe ni Agọ ireti, awon mi-in naa n gbe nibẹ ti won ko ni arun yii ṣugbọn ti wọn ṣi jẹ akanda ti ẹya ara miran pe nija, pẹlu awọn to jẹ talika ti ko le da ọwọ mu lọ sẹnu rara.
Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ àwọn ọmọ onílùú lásìkò ìfẹ̀hónúhàn- Ìjọba Naijiria kìlọ̀ fáwon èèyàn rẹ̀ tó ń gbé ní South Africa
Ikilọ yii lo n waye lẹyin ti alakooso agba kan lati Naijiria fun Johannesburg, sọ pe iwadii fi han pe awon kan n pete iwọde tuntun lagbegbe Gauteng, laaarin ọjọ Aje si Ọjọruu oṣu yii (Monday 27 - Wednesday 29 April).
Erin kọlu ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Oyo, pa èèyàn kan, ẹlòmíì di àwátì
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede.
Ìròyìn Pàtàkì
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn mẹ́wàá tún ti lùgbàdì Covid-19 ní Naijiria? Ohun tí a mọ̀ rèé
Bakan naa ni awọn ẹka ilera kaakiri ipinlẹ Cross River naa ti sọ pe ko si akọsilẹ arun Corona mẹwaa lọdọ awọn.
Wo àwọn ilé tí ìjọba Eko kò fún láǹfàní láti lo iná 'Solar' láì gbàṣẹ àti ìgbésẹ̀ tó yẹ kí o gbé kí o tó ṣe é sílé rẹ
Ina Solar yii ti pọ kaakiri to bẹẹ ti wọn n lo o ni awọn igberiko kiri, ti ọpọ eeyan ko si duro de ina mọnamọna mọ.
Gbọin-gbọin ni a wà lẹ́yìn Makinde bí òkè, àhesọ ọ̀rọ̀ lásán n'ìròyìn tó ní a fẹ́ yọ ọ́ nípò – Ilé Aṣòfin Oyo
Adari ẹgbẹ oṣelu to pọju nile, Họnọrebu Sanjo Adedoyin, to n ṣoju ẹkun Guusu Ogbomoso lo dabaa wi pe ki ile dibo lati kede atilẹyin wọn fun Makinde.
Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn OAU ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń múra ìdánwò, jáde láyé
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ọmọ ọdun mejidinlogun kan to n kẹkọọ imọ iṣẹgun nile ẹkọ kan naa, Timilehin Toromade jade laye loju orun rẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2026 yii.
Ẹ gbà wá o, àwọn agbébọn ti fẹ́ pa wá tán - Àwọn ọ̀dọ́ Gúúsù Kwara figbeta
Nibi ti ọrọ naa ka wọn lara de, awọn ọdọ Guusu Kwara ti wọn n gbe niluu Eko, Ilorin ati awọn ilu mi-in tẹ ọkọ leti wa silẹ lati dara pọ mọ ifẹhonuhan yii.
Ohun tó fàá tí Ààrẹ Kenya fi sọ pé ọmọ Naijiria ò lè sọ èdè òyìnbó dáadáa
Ọrọ yii ti bẹyin yọ tori ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria atawọn ọmọ orilẹede Afirika mii ni wọn ti bu ẹnu ẹtẹ lu Ruto wi pe o n tabuku orilẹede ilẹ Afirika mii.
Ìgbẹ́jọ́ ọmogun 36 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba Tinubu bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ iléeṣẹ́ ológun Naijiria
Olu ileeṣẹ ologun Naijiria to ṣe ifilọlẹ igbẹjọ naa lonii ọjọ Ẹti ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹrin yii sọ pe ẹsun iditẹ eyi to lewu fun aabo orilẹede lẹsun ti wọn fi kan awọn ọmogun naa.
Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yá $516m láti ṣe ọ̀nà láti Sokoto sí Badagry
Ọrọ naa lo wa ninu lẹta kan ti Aarẹ igbimọ aṣofin naa, Godswill Akpabio ka niwaju awọn ọmọ ile.
Ọkùnrin tí ọlọ́pàá ká ẹ̀yà ara èèyàn mọ́ lọ́wọ́ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé
Baba afurasri naa ti kọkọ fẹsun jiji alupupu Boxer Bajaj mẹta, ewurẹ mẹsan an, ẹrọ ilewọ Android mẹrin, epo pupa, silinda gaasi meji, atawọn nnkan mii kan an.
Èèyàn 518 ló kú nínú rògbòdìyàn ètò ìdìbò Ààrẹ Tanzania – Ìwádìí
Igba akọkọ ree ti awọn alaṣẹ yoo mẹnuba iye eeyan to ku ninu ifẹhonuhan to waye lẹyin eto idibo naa.
Tinubu yọ Mínísítà ètò ìṣúná Wale Edun nípò, fi Taiwo Oyedele rọ́pò rẹ̀
Gẹgẹ bi akọwe ijọba apapọ, George Akume, ti ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, minisita meji ni Aarẹ Tinubu yọ nipo ti o si ti rọpo wọn pẹlu.














































































